Orisirisi ibanuje ati kikoro loti ba awon alatileyin egbe agbaboolu Arsenal ni asiko 2016-2017. Fun igba kini ni ogun odun, won ko ni gba boolu pelu awon asiwaju ni Europe ni asiko to n bo, l’ori eleyi tuni wipe aladugbo ati ota ayeraye won, Tottenham Hotspur, se daada juwon lo ni odun yi fun igba kini l’abe oludari Arsene Wenger. Odun yi kan da bi igba ti ibanuje ba subu lu oriburuku fun Arsenal ni. Bi asiko 2016-2017 se lo, ko si enikeni to lero pe ogo aiye Arsenal le gbera nigba ti won pade egbe agbaboolu Chelsea ni irole ana ni papa isere Wembley. Chelsea lo gbegba oke ni asiko 2016-2017, nitori naa, awon oni kalokalo ti fihan wipe ko si ona ti Arsenal le fi na won ni ere boolu ipari agolo FA. Aropin t’eyan, sise ni t’Olorun; gbogbo wa l’ademo pe enu ose (Durella lo so be!)

Nitori ipalara to ba Mustafi, Gibbs, ati akogun Koscielny, oludari Wenger ni lati lo gbe Mertesacker jade ninu ile iwosan lati wa bere ere boolu fun Arsenal ni ale ojo naa. Iyalenu yi kotan sibe, Wenger tun pinu lati jeki Ospina bere l’oju goli fun Arsenal, okan da bi afise l’oju awon alaroye ni. Se lo dabi wipe ofe kan fe gbe agolo FA naa fun Chelsea l’ofe l’ofo.

Ere boolu na bere l’asiko, awon agbaboolu Arsenal n se tiki taka, won ko jeki awon Chelsea fi ese kan boolu, sugbon gbogbo wa la n so l’okan wa pe gbogbo gragra Arsenal ma wale laipe. Beeko lose ri ni iseju kerin nigbati Alexis Sanchez fi owo dari boolu si Aaron Ramsey n’iwaju apoti mejidilogun Chelsea, awon omo Chelsea ganpa bi sigidi fun aaya kan tabi meji nigba ti won ro pe Ramsey ti wo offside sugbon ko fi ese kan boolu ti Sanchez fi wa sare wa gba si abe goli Courtois to fi wo oju ile Chelsea. Kosi eni to koko mo nkan to n sele, sugbon atokun ere boolu, ogbeni Anthony Taylor, sare lo ba oluranlowo atokun soro fun asiko die ko to wa sope Arsenal ti fikan si. Ariwo ta ni papa isere Wembley!

Ere boolu na dun gan, Arsenal ni orisirisi anfani lati gba meta wole ki idaji kini ere boolu na to pari sugbon igbakugba Wellbeck, Ramsey ati Ozil loju goolu Chelsea ko je ko ribe. Eyan gidi ni Wellbeck sugbon ati gba boolu wole dabi imo rocket si ogbeni na. Bi ere boolu na se n lo ni idaji keji, ko si repete to n sele, Diego Costa n se bi o se ma se – were ponbele ni arakunrin na, oniwa bi iwa ehana. Chelsea gbiyanju lati dapada fun Arsenal, sugbon awon omo Wenger ko gba fun won.

Ni iseju ogota mejo, Victor Moses subu ninu apoti mejidilogun Arsenal lati wa gbamabinu tapa penarity, sugbon oje e ko je atokun Anthony Taylor. Taylor  fi paali ofeefee ati paali pupa han Victor, oni ko l’owe ko ma lo s’ile nitori o fe tan atokun je. Ose gbogbo eyan ni kayefi nitori  awon alatileyin egbe agbaboolu Arsenal ti n pariwo pe atokun Taylor ko feran ti egbe boolu won.

Afi bi afise ni iseju aadorin mefa, ogberan Costa se bo se ma n se, o fikansi fun Chelsea lati ko aya awon omo leyin Arsenal s’oke. Goolu na ko ti tutu nigbati Arsenal dapada, Giroud lo s’eto boolu fun Ramsey to f’ori kan mole. Ko si nkankan ti Courtois lese si. O wo ti bolu na se wole ni. Arsenal tun ni anfani lati fin meji kun goolu leyin iyen sugbon ko wole fun won. Arsenal se tiki taka titi  atokun Taylor fun feere pe ere boolu na ti pari – Arsenal s’egun Chelsea! Arsenal ti gbe agolo FA ni odun 2017 lodi si gbogbo aidogba!

Oro fun Arsène Wenger

Kin to ka n le bi waya NEPA, mo ni oro kan tabi meji fun oludari Arsenal, Arsene Wenger: Baba, ese fun gbogbo nkan ti e ti se fun egbe agbaboolu Arsenal sugbon asiko tito lati tesiwaju. Ko si ipari to tun le da to eyi mo laarin Arsene ati Arsenal. Leyin ebe, abuku l’okan, a de ti ripe abuku ti n wole si Wenger lara ni asiko boolu to se pari. Mo feran baba yi gan, mo de fe je ki itan re ni London pari daradara. Ko ni dara ki aroso Wenger pari bi ti eni ti ko mo igba ti igba ti re koja. Ose monsieur Wenger, odigba! #WengerJade

Advertisement